Get Even More Visitors To Your Blog, Upgrade To A Business Listing >>

Awon Orisa Nile Yoruba

Tags: awon orisa osun


Bi a ba n soro nipa Awon orisa nile Yoruba, tabi ka so wi pe ti a ba so nipa awon ibo (awon babanla awon Yoruba), won po sua bi omi ti ko see ka. Amo a o lo anfaani yii lati fi menu ba die lara awon orisa:

 Obatala

Orisirisi oruko ni orisa yii n je: Orisanla, Orisa Ogiyan ni ilu Ejigbo; orisa Aire ni ilu Ikire ati wi pe oun naa lo si n je Aworo Ose ni ilu Ila-Orangun. Funfun, funfun ni nnkan ti orisa yii feran. Efun ni a fii n kun oju re. Ounje re si ni igbin ati obi ifin ti o lado. Omi ti a jip on ni aaro ti o toro nigin ni Obatala feran lati maa mu. Funfun si ni aso awon olusin re. Gbogbo nnkan ti a toka yii n fi Obatala han gege mi orisa mimo ti o tun ni iwa otito. Oriki Obatala lo bayi pe: Obatala a-woro-defe, Osenikan digba eniyan…

Ifa

 Oun naa ni a tun pe ni Orunmila. O je orisa kan to Pataki ninu awon ibo nile Yoruba. Ogbon re po jojo, idi niyi ti won fi maa n kii “Akere finu sogbon, akoniloran bi iyekan eni”. Ifa tun je eleri ipin nitori pe awon Yoruba gbagbo pe Ifa lo wa lodo Eledumare nigba ti olukaluku n yan ipin re. Bi nnkan ba wa di wi pe o ruju ninu irinajo eda nile aye, Ifa ni awon Yoruba yoo to lo fun iwadii ati ibeere ti o ye. Eyi toka si I wi pe eniyan gbogbo ni n beere lowo ifa, Ifa kii beere lowo eni kan. Ko si ohun yoowu ti a ba ba lo si odo re ti ko ni di ero.

Ogun

 Okan ninu awon orisa Ibinu Eledumare ni Ogun. Gbogbo eni ti n ba n lo irin, ti Ogun ni won se. Orisa Ogun ni Ogun I se, ode harau si ni pelu. A gbo wi pe oun lo fi ada owo re lana fun awon orisa yooku lati koja laarin igbo to di pingunpingun. Nigba ti a ba n bo Ogun, gbogbo ode ilu lo gbodo pese. Awon ijoye ilu ko ni gbeyin, bee ni gbogbo awon to n sise to jemo irin gege bi a ti toka si saaju.

 Awon ounje ti won maa n ko wa si idi Ogun niwonyi: Eyan agbado, eyan eree, emu ati aja ti won yoo be si idi Ogun. Won tun ni lati ta mariwo si ibi ojubo Ogun. Oriki Ogun lo bayi pe: Ogun Lakaaye Osinmole, O lomi nile feje we, O laso nile fakisa bora…

Sango

A ti ko nipa orisa ti a n pe ni Sango. E ni anfaani lati ka nipa awon ekunrere alaye ti a ti se nipa [Orisa Sango]

Osun

 Okan ninu awon orisa ti ko see fowo ro seyin naa ni Osun. Obinrin ni, iyawo Sango si ni pelu. Bo tile je ibo Osun maa n waye pelu ayeye ni odoodun, sibe bibo ojoojumo ko kere. Ilu Osogbo ti di ilu ti gbogbo eniyan ka si ibi to wa fun gbigbe Osun laruge. Eleyii si ti je ki orisa Osun gbayi pupo.
Sugbon kii se ilu Osogbo nikan ni won ti n bo Osun. Orisa yii wa laarin ibo jakejado ile Yoruba. Nibi ti odo Osun gan-an ko ba si, won a maa so oruko odo miiran ni odo Osun lati maa bo orisa yii nibe.
Awon nnkan ti won fi n bo Osun ni wonyi: obi, akuko, igbin, agbo tabi ohunkohun ti awon ti Osun ti se loore lodun esin ba fi je eje. Orisa olomo ni Osun. Igba gbogbo ni awon agan maa n toro omo lati odo re ti won si n ri ayo gba. Oriki Osun lo bayii pe: Osun yeeye o, Osun raamu, Raamu onibu owo, Afide-re-wemo, yeye o…

Esu 

A ti ko nipa orisa ti a n pe ni Esu. E ka nipa awon ekunrere alaye ti a ti se nipa [Orisa Esu]

Nje O Ti Ka:
1. Ami Ohun Ati Apeere
2. Aro Dida (Yoruba Dye Making)
3. Apoti Alakara (Debo Awe)

                                               



This post first appeared on Online Yoruba Teacher, please read the originial post: here

Share the post

Awon Orisa Nile Yoruba

×

Subscribe to Online Yoruba Teacher

Get updates delivered right to your inbox!

Thank you for your subscription

×